Jóòbù 29:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀mi, ọrun mi sì padà di titun ní ọwọ́ mi’

21. “Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọna sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.

22. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀mọ́; ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.

23. Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí péwọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò wọn a sìmu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀-kúrò.

Jóòbù 29