Jóòbù 29:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn ọmọ ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọnsì lẹ̀mọ́ èrìgì ẹnu wọn.

11. Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súrefún mi,àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi;

12. Nítorí mo gbà talákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́,àti aláìní baba, tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un

13. Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmisì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.

14. Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́mi dà bí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.

15. Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀fún amúkùnún.

16. Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣeìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí.

17. Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn,mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.

18. “Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóòkú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí i yanrìn.

Jóòbù 29