1. Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jóòbù sì tún tẹ̀ ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:
2. “Áà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tíó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pamímọ́;
3. Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;
4. Bí mo tirí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbàtí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi
5. Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
6. Nígbà tí èmi fi òrí àmọ́ n wẹ ìsísẹ̀ mi,àti tí àpata ń tú ìsàn òróró jáde fún mi wá.