13. “Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọnaninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmáre:
14. Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fúnidà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.
15. Àwọn tí ó kú nínú tirẹ̀ ni a ósìnkú nínú àjàkálẹ̀-àrùn: àwọnopó rẹ̀ kì yóò sì sunkún fún wọn.
16. Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tíó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;
17. Àwọn ohun tí ó tò jọ àwọnolóòótọ́ ni yóò lò ó; àwọnaláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.
18. Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,àti bí ahéré tí olùsọ́ kọ́.