8. Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkù àwọsánmọ̀rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
9. Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹàwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
10. Ó fi idẹ yí omi òkun ká, títí déààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11. Ọ̀wọ̀n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yàwọ́n sì ìbàwí rẹ̀.
12. Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi òkun; nípaòye rẹ̀, ó gé Ráhábù sí wẹ́ẹ́wẹ́.
13. Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run níọ̀sọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti dá ejò wíwo nì.
14. Kíyèsí i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”