Jóòbù 24:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọ̀dá àti òru ní ímú omi ojọ-didi gbẹ, bẹ́ẹ̀ní isà òkú írun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

20. Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòròní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀,a kì yóò rántí ènìyàn búburúmọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi;

21. Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tíkò ṣe rere sí opó.

22. Ṣùgbọ́n ó fi ipá Ọlọ́run rẹ̀ fà alágbáralọ pẹ̀lú; Ó dìde, kò sí ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ dá lójú.

23. Ọlọ́run sì fi ìwà àìléwu fún un,àti nínú èyí ní a ó sì tì i lẹ́yìn, ojúrẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.

24. A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀; wọ́nkọjá lọ, a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sìmú wọn kúrò ní ọ̀nà, bí àwọnẹlòmìíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí sírì itú ọkà bàbà.

25. “Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsìn yìí,ta ni yóò mú mi ní èké,tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”

Jóòbù 24