Jóòbù 22:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmáarèpé, olódodo ni ìwọ? Tàbí èrèkí ni fún un, ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

4. “Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rùỌlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?

5. Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀rẹ láìníye?

6. Nítòótọ́ ìwọ bèèrè fún ààbò niọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọsì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.

7. Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọsì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.

Jóòbù 22