Jóòbù 22:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Èé ṣe tí òkùnkùn, fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tíìwọ kò fi lè ríran; Èé ṣe tíọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12. “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?Ṣá wò orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

13. Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

14. Àwọ̀sánmọ̀ tí ó nípọn ni ìborafún un, tí kò fi lè ríran; ó sì rìn nínú àyíká ọ̀run.

Jóòbù 22