22. Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́ jọ lé e lórí.
23. Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹunỌlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí,nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́,yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
24. Yóò sá kúrò lọ́wọ́ ohun ogunìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
25. O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idàdídán ní ń jáde láti inú òróòrowá: Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀.
26. Òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́fún ìṣúra rẹ̀; iná ti a kò fẹ́ níyóò jó o run: yóò sì jẹ èyí tí ókù nínú àgọ́ rẹ̀ run.