Jóòbù 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, dáhùn, ó sì wí pé:

2. “Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀tì; ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ

3. Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bíẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?

4. Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínúìbínú rẹ̀; kí a ha kọ ayé sílẹ̀nítorí rẹ̀ bi? Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?

5. “Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni aó pa kúrò, Ọ̀wọ́ iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.

Jóòbù 18