Jóòbù 17:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú.

10. “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ sì tún bọ̀ nísinsin yìí;èmi kò le rí ọlọgbọ́n kan nínú yín.

11. Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìro mi ti fàjá, àní ìro ọkàn mi.

12. Àwọn ènìyàn wọn yí ìsọ́ òru diọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.

13. Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilémi; mo ti tẹ́ ìbùsùn mi sínú òkùnkùn.

14. Èmi ti wí fún ìdibàjẹ́ pé, ìwọ nibaba mi, àti fún kòkòrò pé,ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,

15. Ìrètí mi ha dà nísinsinyí? Bí ó ṣeti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?

16. Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”

Jóòbù 17