8. Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,ẹni aláìsẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9. Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú.
10. “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ sì tún bọ̀ nísinsin yìí;èmi kò le rí ọlọgbọ́n kan nínú yín.
11. Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìro mi ti fàjá, àní ìro ọkàn mi.