24. Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú unbẹ̀rù, wọ́n ó sì sẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ímúra ogun.
25. Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdìsí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmáarè,
26. Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn giga, àní fiìké kòóko àpáta rẹ̀ tí ó nipọn kọlù ú.
27. “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀lojú, o sì ṣe jabajaba ọ̀rá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28. Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété,àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbémọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà.