Jòhánù 9:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àwọn kan wí pé òun ni.Àwọn elòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.”Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.”

10. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”

11. Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jésù ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kùn mí lójú, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Sílóámù, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”

12. Wọ́n sì wí fún un pé, “Òun náà ha dà?”Ó sì wí pé, “Èmi kò mọ̀.”

13. Wọ́n mú ẹni tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí wá sọ́dọ̀ àwọn Farisí.

Jòhánù 9