Jòhánù 9:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú.

19. Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?”

20. Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú:

Jòhánù 9