Jòhánù 8:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń se ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”

30. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

31. Nítorí náà Jésù wí fún áwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin mi nítòótọ́.

32. Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

Jòhánù 8