26. Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”
27. Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn.
28. Lẹ́yìn náà Jésù wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé ẹ̀mi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí.
29. Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń se ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”
30. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.
31. Nítorí náà Jésù wí fún áwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin mi nítòótọ́.
32. Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”
33. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-Ọmọ Ábúráhámù ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”
34. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.
35. Ẹrú kì í sìí gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé
36. Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.
37. Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Ábúráhámù ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè nínú yín. Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀
38. Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”
39. Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ábúráhámù ni baba wa!”Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Ábúráhámù
40. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Ábúráhámù kò ṣe èyí.
41. Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “A kò bí wa nípa panṣágà: A ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”
42. Jésù wí fún wọn pé, “Ìbáṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi.
43. Èé ṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
44. Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké.