Jòhánù 7:51-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

51. “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

52. Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Gálílì bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Gálílì dìde.”

53. Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

Jòhánù 7