Jòhánù 7:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mósè, ẹ ha ti ṣe ń bínú sími, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ṣáṣá ní ọjọ́ ìsinmi?

24. Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa se ìdájọ́ òdodo.”

25. Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jérúsálẹ́mù wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí?

26. Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nkankan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, Èyí ni Kírísítì náà?

Jòhánù 7