1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.
2. Adágún omi kan sì wà ní Jérúsálẹ́mù, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Bẹtiṣáídà ní èdè Hébérù, tí ó ní ìloro márùn-ún.
3. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dúbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti alárùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi.
4. Nítorí angẹ́lì a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú àrùnkárùn tí ó ní.
5. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì.
6. Bí Jésù ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”