Jòhánù 21:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Símónì Pétérù wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

4. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jésù dúró létí òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jésù ni.

5. Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní oúnjẹ díẹ̀ bí?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”

6. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin ó sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.

7. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jésù fẹ́ràn wí fún Pétérù pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Símónì Pétérù gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú òkun.

8. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja.

9. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yinná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.

10. Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.”

11. Nítorí náà Símónì Pétérù gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́taléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya.

12. Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.

Jòhánù 21