Jòhánù 15:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

23. Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú.

24. Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàárin wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra àti èmi àti Baba mi.

25. Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

Jòhánù 15