Jòhánù 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni Olùtọ́gbàse.

2. Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò: gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èṣo, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i.

3. Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.

4. Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi.

Jòhánù 15