Jòhánù 11:55-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

55. Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì sún mọ́ etílé: ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbéríko sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́.

56. Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jésù, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹ́mpílì, wí pé, “Ẹ̀yin ti rò ó sí? Pé kì yóò wá sí àjọ?”

57. Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn baà lè mú un.

Jòhánù 11