Jòhánù 1:49-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Nígbà náà ni Nàtaníẹ́lì sọ ọ́ gbangba pé, “Rábì, Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”

50. Jésù sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀ jù ìwọ̀nyí lọ.”

51. Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”

Jòhánù 1