13. Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn
14. Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí ṣílò sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé Tẹ́ḿpìlì nínú èyí tí ẹ ní ìgbàgbọ́, àyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín.
15. Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Éfúráímù.’
16. “Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ.
17. Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù?
18. Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná síi, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn Ọlọ́run àjòjì láti mú mi bínú sókè.