19. Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Ísírẹ́lìpadà wá pápá oko tútù rẹ̀òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí kámẹ̀lì àti Básánì,a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkèÉfúráímù àti ní Gílíádì
20. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”ni Olúwa wí,“À ó wá àìṣedéédé ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì,ṣùgbọ́n a ki yóò rí ìkankan;àti ẹṣẹ Júdà a ki yóò sì rí wọnnítorí èmi yóò dáríjìn àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dásí.
21. “Kọlu ilẹ̀ Mérátamù àti àwọntí ó ń gbé ní Pékódì.Kọlùú pa á, kí o sì párun pátapáta,”ni Olúwa wí“Ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ.
22. Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náàìrọ́kẹ̀rẹ̀ ìparun ńlá.