20. “Kéde èyí fún ilé Jákọ́bù,kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà.
21. Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aláìlóye àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,tí ó lójú ti kò fi rírantí ó létí ti kò fi gbọ́ran.
22. Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí.“Kò ha yẹ kí èyin ó wárìrì níwájú mi bí?Mo fi yanrìn pààlà òkun,èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.
23. Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
24. Wọn kò sọ fún ara wọn pé,‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédéé.’
25. Àìṣedéedée yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.
26. “Láàrin ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wàtí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.