9. Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò níkó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?
10. Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Ísọ̀ sí ìhòòhòèmi kò ní bo ibi ìkọ̀kọ rẹnítorí kí o máa baà fi ara rẹ pamọ́.Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àtiàwọn ará ilé rẹ yóò parun.Wọn kò sì ní sí mọ́.
11. Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀èmi yóò dábòbo ẹ̀mí wọn.Àwọn opó rẹ gan an lè gbékẹ̀lẹ́ mi.”
12. Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ife náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mu un.