Jeremáyà 48:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,ìwọ tí ń gbé ní Áróà.Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’

20. Ojú ti Móábù nítorí tí a wó o lulẹ̀,ẹ hu, sì kígbe síta!Ámónì kéde péa pa Móábù run.

21. Ìdájọ́ ti dé sí Pílátéùsórí Hólónì, Jáhásà àti Mẹ́fátì,

22. sórí Díbónì, Nébò àti Bẹti Díbílátaímù

23. sórí Kíríátaímù, Bẹti Gámù àti Bẹti Méónì,

Jeremáyà 48