Jeremáyà 43:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ní Táfánésì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá:

9. “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu ọ̀nà ààfin Fáráò ní Táfánésì.

10. Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi yóò ránsẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ.

11. Yóò gbé ogun sí Éjíbítì; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà.

Jeremáyà 43