Jeremáyà 43:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí náà, Jóhánánì ti Káréà àti àwọn ọ̀gágun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Júdà.

5. Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti àwọn ọ̀gágun sì ko àwọn àjẹkù Júdà tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Júdà láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.

6. Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ Ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusàrádánì tí ó jẹ́ adarí ogun ọ̀wọ́ tí ó jẹ́ olùsọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Jedaháyà ọmọ Élíkámù, ọmọ Sáfánì, àti Jeremáyà wòlíì náà àti Bárúkù ọmọ Néríà.

7. Nítorí náà, wọn wọ Éjíbítì pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Táfánésì.

8. Ní Táfánésì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá:

Jeremáyà 43