Jeremáyà 35:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jónádábù ọmọ Rékábù pa òfin baba wọn mọ́ tí ó palásẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

17. “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Júdà, àti sórí gbogbo olùgbé Jérúsálẹ́mù nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

18. Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún ìdílé Rékábù pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jónádábù baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó palásẹ fún un yín.’

19. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, pé: ‘Jónádábù ọmọ Rékábù kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”

Jeremáyà 35