15. Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísisiyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sími.
16. Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jónádábù ọmọ Rékábù pa òfin baba wọn mọ́ tí ó palásẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’
17. “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Júdà, àti sórí gbogbo olùgbé Jérúsálẹ́mù nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”
18. Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún ìdílé Rékábù pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jónádábù baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó palásẹ fún un yín.’
19. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, pé: ‘Jónádábù ọmọ Rékábù kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”