Jeremáyà 34:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò fetí sími nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrin ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrin ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-àrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.

18. Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọ̀rọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrin ìpín méjì náà.

19. Àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ti Jérúsálẹ́mù, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrin àwọn ìpín méjèèjì náà.

20. Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́.

21. “Sédékáyà Ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Júdà ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Bábílónì tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín.

22. Wò ó èmi ó pàṣẹ ni Olúwa wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì baà jà, wọn ó sì kóo, wọn ó fi iná jóo. Èmi ó sì sọ ìlú Júdà dí ahoro.”

Jeremáyà 34