Jeremáyà 22:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ìwọ tí ń gbé ‘Lẹ́bánónì,’tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kédárì,ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!

24. “Dájúdájú bí èmi ti wà láàyè,” ni Olúwa wí, “Bí Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.

25. Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì àti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì.

Jeremáyà 22