Jeremáyà 2:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgàrẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga niàti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.

21. Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bíàjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá,Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí midi àjàrà búburú àti aláìmọ́?

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódàtí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹàbàwọ́n àìṣedéédéé rẹ sì ń bọ̀ níwájú mi,”ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.

23. “Báwo ni o ṣe le lọ sọ pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́;Èmi kò ṣáà tẹ̀lé àwọn Báálì’?Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;wo ohun tí o ṣe.Ìwọ jẹ́ abo ìbákasíẹ̀tí ń sá sí ìhín sọ́hùn ún.

24. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń gbé ihàtí ń fa ẹ̀fúùfù nínú ìfẹ́ inú rẹ̀ta ni ó le è mu dúró ní àkókò rẹ̀?Kí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ílé e má ṣe dára wọn lágaranítorí wọn ó ò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.

Jeremáyà 2