11. “Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe.’
12. Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò se nǹkànkan, àwa yóò tẹ̀ṣíwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọkan wa, yóò tẹ̀lé agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”
13. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Ẹ bèèrè nínú orílẹ̀ èdè, ẹni tíó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?Ohun tí ó burú gidi ni wúndíá Ísírẹ́lì ti ṣe.
14. Ǹjẹ́ omi ojo rírí Lébánónì yóò diàwátì láti ibi àpáta? Sí omi tútùtí ó jìnnà sí orísun rẹ yóò kọ̀ láti ṣàn bí?
15. Síbẹ̀ ni àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi,wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà aṣántí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn àti ọ̀nà wọn àtijọ́.Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́ àti ní ojú tí a kò kọ́