Jeremáyà 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá wí pe:

2. “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

3. Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.

4. Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

5. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

Jeremáyà 18