Jeremáyà 13:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,Èmi yóò sunkún ní ìkọ̀kọ̀nítorí ìgbéraga yín;Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,tí omi ẹkún, yóò sì máa ṣàn jáde,nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18. Sọ fún Ọba àti ayaba pé,“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

19. Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní Négéfì ni à ó tì pa,kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti sí wọn.Gbogbo Júdà ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,gbogbo wọn ni a ó kó lọ pátapáta.

Jeremáyà 13