1. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Jósẹ́fù pé, “Baba rẹ ń sàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Mánásè àti Éfúráímù lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀.
2. Nígbà tí a sọ fún Jákọ́bù pé, “Jósẹ́fù ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Ísírẹ́lì rọ́jú dìde jókòó lórí ìbùsùn rẹ̀.