Jẹ́nẹ́sísì 47:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Jósẹ́fù wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Fáráò, irúgbìn rè é, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà.

24. Ṣùgbọ́n nígbà tí ire oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdá kan nínú ìdá márùn-ún rẹ̀ fún Fáráò. Ẹ le pa ìdá mẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.”

25. Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, Ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Fáráò.”

26. Nítorí náà Jósẹ́fù sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Éjíbítì, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òni olónìí-pé, ìdá kan nínú ìdá márùn-ún irè oko jẹ́ ti Fáráò, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò.

27. Àwọn ará Ísírẹ́lì sì tẹ̀dó sí Éjíbítì ní agbégbé Gósénì. Wọ́n ní ohun-ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye.

28. Jákọ́bù gbé ní Éjíbítì fún ọdún mẹ́tadínlógún (17) iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tàdín ní àádọ́jọ (147).

29. Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Ísírẹ́lì láti kú, ó pe Jósẹ́fù, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún-un pé, “Bí mo bá rí ojú rere ni oju rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Éjíbítì,

30. Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Éjíbítì kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.”Jóṣẹ́fù sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.”

31. Jákọ́bù wí pé, “Búra fún mi,” Jósẹ́fù sì búra fún un. Ísírẹ́lì sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé ori ìbùsùn rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 47