7. Ṣùgbọ́n Érì àkọ́bí Júdà ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á.
8. Nígbà náà ni Júdà wí fún Ónánì, “Bá aya arákùnrin rẹ lò pọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin-ìn rẹ.”
9. Ṣùgbọ́n Ónání mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀.
10. Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú.
11. Nígbà náà ni Júdà wí fún Támárì, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣélà yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tó kù.” Nígbà náà ni Támárì ń lọ gbé ilé baba rẹ̀.
12. Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Júdà, ọmọbìnrin Súà sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Júdà sì pé, ó gòkè lọ sí Tímínà, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hírà ará Ádúlámù tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ.
13. Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Támárì pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Tímínà láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.”
14. Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́. Ó sì jókòó sí ẹnu ibodè Énáímù, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Tímínà. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣélà ti dàgbà, ṣíbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
15. Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀.
16. Láì mọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́, ó wí pé,“Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè bá mi lò pọ̀.”
17. Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran.”Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?”