7. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojúkan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwon méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.
8. Báyìí ni Ísọ̀ tí a tún mọ̀ sí Édómù tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀ èdè oloke tí Ṣéírì.
9. Èyí ni ìran Ísọ̀ baba àwọn ará Édómù ní àwọn orílẹ̀ èdè olókè Ṣéírì.
10. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísọ̀:Élífásì ọmọ Ádà aya Ísọ̀ àti Rúélì, ọmọ Báṣémátì tí í ṣe aya Ísọ̀ pẹ̀lú.
11. Àwọn ọmọ Élífásì ni ìwọ̀nyí:Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Gátamù, àti Kénásì.
12. Élífásì ọmọ Ísọ̀ sì tún ní àlè tí a ń pè ní Tímúnà pẹ̀lú, òun ló bí Ámálékì fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ọmọ Ádà aya Ísọ̀.
13. Àwọn ọmọ Rúélì:Náhátì, Ṣérà, Ṣámà àti Mísà. Àwọn ni ọmọ-ọmọ Báṣémátì aya Ísọ̀.
14. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Óhólíbámà ọmọbìnrin Ánà ọmọ-ọmọ Ṣíbéónì: tí ó bí fún Ísọ̀:Jéúsì, Jálámì àti Kórà.
15. Wọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Ísọ̀:Àwọn ọmọ Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀:Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Kénásíà,