25. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ánà:Dísónì àti Óhólíbámà (Àwọn ọmọbìnrin ni wọn).
26. Àwọn ọmọ Dísónì ni:Hémídánì, Ésíbánì, Ítíránì àti Kéránì.
27. Àwọn ọmọ Éṣérì:Bílíhánì, Ṣááfánì, àti Ákánì.
28. Àwọn ọmọ Díṣánì ni Húsì àti Áránì.
29. Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hórì:Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Áná,
30. Dísónì Éṣérì, àti Díṣánì. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Órì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Ṣéírì.
31. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní Édómù kí ó tó di pé a ń jẹ ọba ní Ísírẹ́lì rárá: