Jẹ́nẹ́sísì 35:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Àwọn ọmọ Ṣílípà ìránṣẹ́-bìnrin Líà:Gádì àti Áṣérì.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jákọ́bù bí ní Padani-Árámù.

27. Jákọ́bù sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni Mámúrè ní tòsí i Kiriati-Árábà (Hébúrónì). Níbi tí Ábúráhámù àti Ísáákì gbé.

28. Ẹni ọgọ́sán-an (180) ọdún ni Ísáákì.

29. Ísáákì sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jákọ́bù, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́-ogbó rẹ̀. Ísọ̀ àti Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin-ín.

Jẹ́nẹ́sísì 35