Jẹ́nẹ́sísì 32:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jákọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”

29. Jákọ́bù sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà ṣáà dáhùn pé, “Èéṣe tí o n béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó ṣúre fún Jákọ́bù níbẹ̀.

30. Jákọ́bù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pẹ́núẹ́lì pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, ṣíbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”

31. Bí ó sì ti ń kọjá Pẹ́núẹ́lì, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 32