Jẹ́nẹ́sísì 32:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Ísọ̀ bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ,

18. Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jákọ́bù ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Ísọ̀ olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”

19. Jákọ́bù sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Ísọ̀ nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 32