1. “ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí agbègbè mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀; gbogbo agbègbè náà ni yóò jẹ́ mímọ́.
2. Lára èyí, apákan ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí o jẹ́ ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní ó gbọdọ̀ wà fún ibi ìyàsímúmọ́ fún Ọlọ́run, pẹ̀lú ibẹ̀ tí ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún ilẹ̀ tí ó yí ibi mímọ́ náà ká. Ilẹ̀ tí ó yí i ká yìí yóò wà bẹ́ẹ̀ láì lò ó.