24. “ ‘Nínú èyíkéyi èdè-àìyedè, àwọn Àlùfáà ní ó gbọdọ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ fún gbogbo àṣẹ, wọn sì gbọdọ̀ lo ọjọ ìsinmi mi ní mímọ́.
25. “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ bàbá tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.
26. Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje.
27. Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti se ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Ọba wí.